Shuahib Afolabi Salisu: Òótọ́ ni mo súnmọ́ Gómìnà ṣùgbọ́n mo kúnjú òṣùwọ̀n ni mo ṣe gba láti díje dupò

Àkọlé fídíò, Shuahib Afolabi Salisu: Òótọ́ ni mo súnmọ́ Gómìnà ṣùgbọ́n mo kúnjú òṣùwọ̀n ni mo ṣe gba
Published

Ẹgbẹ APC nikan lo fẹ́ ẹ ku ninu gbogbo ẹgbẹ nipainlẹ Ogun bayii- Omo Yayi

Alhaji Shuahib Afolabi Salisu to n dije dupo aṣojuṣofin fun ẹkun aarin gbungbun ipinle Ogun ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun to n ṣẹlẹ ni ipinlẹ Ogun bayii.

O mẹnuba iriri rẹ ninu oṣelu lati kekere titi di asiko yii.

O sọ awọn ipenija, aṣẹyọri ati ikuna to ti koju ninu iṣelu titi di asiko yii ki awọn ọdọ le kọ ẹkọ ti o yẹ.

Omọ Yayi tun ṣalaye ohun to ni lọkan lati ṣe fun ọdọ, awọn obinrin ati awọn Oludibo lapapọ.

O mẹnuba ohun to maa jẹ ki ara rọ gbogbo ilu lasiko yii.

Bakan naa ni Shuahib Afolabi Salisu sọrọ lori ibi ti iselu ipinlẹ Ogun dẹ duro ati ajọṣepọ to wa laarin Gomina Dapo Abiodun ati awọn ẹka iṣẹjoba to ku nibẹ.

O ni pe ko si rukerudo ninu ile igbimọ Aṣofin ni ipinlẹ Ogun bayii.