Mothers day: Lẹ́yìn Olorun, Ìyá mi ló kù- Papa Ajasco, Abiodun Ayeyinka

Àkọlé fídíò, Mothers day: Lẹ́yìn Olorun, Ìyá mi ló kù- Papa Ajasco, Abiodun Ayeyinka
Published

Mo lè gbá eégun léti, kí n sọ oko fun Adajọ ti Iya mi ba ti wa lẹyin mi- Kosoko Kunbi

Eẹmeji lọdun ni awọn ọmọ Naijiria maa n ṣe ayajọ ọjọ Iya Rere.

Ikan pẹlu awọn ara United kingdom ati ikeji pẹlu awọn ara America ni wọn fi n sami iya ni awujọ.

BBC Yoruba jade lọ gba ọrọ iwuri nipa awọn iya, awọn ọmọ to ti dagba ti wọn ti di gende fọnrere nipa iya to bi wón to dẹ duro tọ wọn, ilẹ kun.

Demopum
Iyaniwura

Gbajugbaja onkorin Juju ni, Sir Shina Peters royin ohun ti oju iya ré ri ki o to bi oun saye léyin ọdun mẹta ati osu meji ninu oyun pẹlu irora.

O ni iya oun ti ro iku ki Olodumare to fi aanu tu u silẹ.

Iyaniwura

Kosọko Kunbi to jẹ akọrin fi orin dara pe oun le gba eegun leti ki oun sọ okuta lu Adajọ ṣugbọn ọkan rẹ balẹ ti iya ba ti wa lẹyin rẹ.

Papa Ajasco iyaniwura

Abiodun Adeyinka to jẹ gbajugbaja oṣere ti gbogbo eeyan n pe ni Papa Ajasco naa sọrọ lori pataki Iya.

O royin bi iya rẹ ṣe sare kiri to fun un ko to le di eeyan laye.

Iyaniwura

Owomoyela Oluwatobi to jẹ adẹrinpoṣonu naa ni pe ti oun bati pe iya oun lẹẹkan, igba mẹwaa lo n da oun lohun.

Nigbati Oluwasegun Adeyemi naa tun sọrọ lori ipa ti iya ko ninu titọ oun si ilana igbọran.

O ni iya oun lo kọ oun ni imọ ati oyr ti a fi n gbe nile aye pẹlu ẹgba.

Iyaniwura

Ni afikun, Egbeleke Ademola ti oun naa jẹ adẹrinposonu naa ṣalaye pe, ọpọ igba ni Baba oun n gbiyanju ṣugbon to ba ya a sọ pe ko si mọ ni eyi ti iay oun a ṣi tiraka sii lati dide iranlọwọ.

Iyaniwura

Otolorin Kehinde ti oun naa tun je aderinposonu naa sọ bi iya rẹ ti ṣe fẹ ẹ lu u pa nitori pe o ya 'Tatoo'si ara ni eyi ti iya rẹ ko fẹ.