Mo fẹ́ máa polongo oúnjẹ ilẹ̀ wa ló jẹ́ kí n máa fi oúnjẹ bíi àmàlà àti ẹ̀bá ya àwòrán
Published
Haneefah jẹ ayaworan to ma n lo ounjẹ orilẹ-ede Naijiria bii amala, ẹba, ẹfọ, ewedu, ọgbọnọ, ṣaki, atarodo ati bẹbẹ lọ lati fi ya aworan.
Nigba ti ikọ ileeṣẹ iroyin BBC ṣabẹwo si Haneefa, o ni awọn alatilẹyin oun loju opo Instagram lo ru oun soke lati maa ya aworan naa.
O tẹsiwaju pe “Ohun to fun mi ni imisi lati bẹrẹ si n ya aworan pẹlu ounjẹ ni pe mi o tii ri ẹnikẹni to n fi ounjẹ ilẹ wa ya aworan.”
Haneefah sọ bi o ṣe ma n ya aworan rẹ ati iriri rẹ lasiko igbele Covid-19.
Ẹ wo fidio yii fun ẹkunrẹrẹ.