You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwa Egba la lajú jù ní gbogbo Nàìjíríà, Mo lè fi gbogbo ẹnu sọ ọ́ - Alake ti Egba
Kabiyesi Alake ti ilu Egba ni ilẹ Yoruba gba alejo BBC yoruba ní ààfin rẹ̀.
Ninu fidio yii, Ọba Adetoun Gbadebọ mẹnu ba kulẹ kulẹ awọn awuyewuye to n lọ lode nigba ti wọn kọkọ gbero ṣiṣe agbekalẹ ikọ Amotekun fun awọn ipinlẹ Yoruba.
"Nígbà tọ̀rọ̀ àbò dé ibi tó dé ni àwọn àgbààgbà Yorùbá dìde sí i. Wọn para pọ lati wa ọna abayọ si abo to ti di nkan itan nilu".
- Ṣeyi Makinde ṣé ìfilọ́lẹ̀ àwọn olùdarí ìbùdókọ́, ó yan Auxilliary lálaga ìgbìmọ̀
- Aláàfin ìlú Oyo, Ikú Bàbá Yèyé tún bímọ tuntun làǹtì lanti
- Ẹ̀ṣọ́ Amotekun ní láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ọlọ́pàá agbègbè- Ọ̀gá ọlọ́pàá Naijiria
- Ìbẹ̀rù nípa Amotekun ló ń mú káwọn èèyàn kan máa wí ìwíkùwí - Soyinka
- Àwọn adájọ́ àgbà ilẹ̀ Yoruba dá àba kí ìkọ̀ Amotẹkun máa lo ìbọn
Alake ni "ni ilẹ Yoruba, nkankan naa ni gbogbo wa patapata, ká máa gbé ní ìrẹ́pọ̀ láì wo bí oníkálùkù ṣe ń sin Ọlọ́run".
ọba Adetoun ṣalaye pe Nigba ti wọn kọkọ n gbero Amotekun ti wọn sọ ọ jade, iha ti awọn ẹlẹsin nilu kọ si i wá latari pe ko si imọ to to nipa ohun ti wọn n sọ.
O ni "béèyàn kan bá rò pé kò sẹ́ni tí yóò mu òun torí ẹ̀sìn, ẹgbẹgbẹ̀rún ló ma mú u". Nitori naa o tẹpẹlẹ mọ gbigbe ni irẹpọ nilẹ Yoruba.
Producer: Yemisi Oyedepo àti Bayo Odukoya