Àwa Egba la lajú jù ní gbogbo Nàìjíríà, Mo lè fi gbogbo ẹnu sọ ọ́ - Alake ti Egba

Àkọlé fídíò, Kò sí ǹkan tó ń jẹ́ ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ tàbí ìmọ̀le nínú àgbékalẹ̀ Amotekun - Alake ti Egba
Published
Alake ti ilu Egba

Oríṣun àwòrán, HRM Oba M A A Gbadebo CFR, The Alake of Egbaland.

Kabiyesi Alake ti ilu Egba ni ilẹ Yoruba gba alejo BBC yoruba ní ààfin rẹ̀.

Ninu fidio yii, Ọba Adetoun Gbadebọ mẹnu ba kulẹ kulẹ awọn awuyewuye to n lọ lode nigba ti wọn kọkọ gbero ṣiṣe agbekalẹ ikọ Amotekun fun awọn ipinlẹ Yoruba.

"Nígbà tọ̀rọ̀ àbò dé ibi tó dé ni àwọn àgbààgbà Yorùbá dìde sí i. Wọn para pọ lati wa ọna abayọ si abo to ti di nkan itan nilu".

Aworan Aarẹ Muhammadu Buhari ati Alake

Oríṣun àwòrán, Yetunde Olugbenga

Alake ni "ni ilẹ Yoruba, nkankan naa ni gbogbo wa patapata, ká máa gbé ní ìrẹ́pọ̀ láì wo bí oníkálùkù ṣe ń sin Ọlọ́run".

ọba Adetoun ṣalaye pe Nigba ti wọn kọkọ n gbero Amotekun ti wọn sọ ọ jade, iha ti awọn ẹlẹsin nilu kọ si i wá latari pe ko si imọ to to nipa ohun ti wọn n sọ.

O ni "béèyàn kan bá rò pé kò sẹ́ni tí yóò mu òun torí ẹ̀sìn, ẹgbẹgbẹ̀rún ló ma mú u". Nitori naa o tẹpẹlẹ mọ gbigbe ni irẹpọ nilẹ Yoruba.

Aafin Alake ti Egba

Producer: Yemisi Oyedepo àti Bayo Odukoya