Ọkọ̀ kan tàkìtì nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé lẹ́bá afárá Third Mainland l'Èkó

Iṣẹlẹ ijamba ọkọ nilu Eko
Àkọlé àwòrán, Ajọ LASTMA ko sọ boya ẹnikẹni ṣeṣe ninu ijamba naa
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ijamba ọkọ kan ti waye lagbegbe Olopomeji, ni abawọle afara Third Mainland to wa ni ilu Eko.

Ajọ to n risi igbekogbodo ọkọ ni ipinlẹ naa, LASTMA fi idi iṣẹlẹ ọhun mulẹ loju opo Twitter rẹ.

Ajọ naa rọ awọn eeyan to n gba agbegbe ọhun lati ṣọra nitori sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ to ti n korajọ lojuko iṣẹlẹ ọhun.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ọkọ Volkswagen to ni nọmba idanimọ SMK 46EH ti ilu Eko lo takiti, to si fi ẹyin lelẹ.

Iṣẹlẹ ijamba ọkọ nilu Eko

Ajọ LASTMA ko sọ boya ẹnikẹni ṣeṣe ninu ijamba naa.

Iṣẹlẹ ijamba ọkọ nilu Eko

Awọn oṣiṣẹ ajọ LASTMA ti wa nibi ti ijamba naa ti waye ti wọn si ti n ṣe iranwọ fun ti iṣẹlẹ naa ṣẹ si.

Àkọlé fídíò, Illegal Rehab Centre: A le ni ogójì tí wan n kó 'sinú ìyará kékeré kan níle Ọlọrẹ