Premier League: Ọ̀mì ayò kan ni Man U àti Liverpool gbá!

Premier League

Oríṣun àwòrán, Inpho

Àkọlé àwòrán, Marcus Rashford ló kọ́kọ́ gbá bọ́ọ́lù wọ inú àwọn fún Manchester United, kí Adam Lallana tó gbá bọ́ọ̀lù wọnú àwọ̀n fún Liverpool.
Published

Ọmi ayo kan naa ni Manchester United ati Liverpool gba ni idije Premier League to n lọ lọwọ.

Eyi ko sẹyin bi ikọ Liverpool ko se le e fakọyọ gẹgẹ bi ikọ ti wọn ko tii na fun igba mejidinlogun ni idije Premier League.

Marcus Rashford ti ikọ Manchester United lo koko gba bọọlu sinu awọn, ki saa kini ifẹsẹwọnsẹ naa.

O ku isẹju marun un ki ifẹsẹwọnsẹ naa pari ni Adam Lallana ti ikọ Liverpool fi ọba le fun wọn, ti ifẹsẹwọnsẹ naa si pari si ọmi ayo kan(1-1).