Yorùbá dùn lédè, sáré pé gbólóhùn yìí wò tóo bá dá ara rẹ lójú

Published

Ọ̀bọ ń gbọ́bọ g'ọ̀pẹ - O yá, ìwọ naa gbiyanju ẹ wo f'awọn ọmọ rẹ.

Ede Yoruba kun fun owe, aṣayan ọrọ, akanlo ede, afiwe ọrọ ati awọn ọrọ akọnilẹnu.

Ọrọ akọnilẹnu jẹ gbolohun ọrọ ti a to papọ ti a maa n sare sọọ ki eeyan le ṣe aṣiṣe tabi fihan pe o dangajia mimu ede Yoruba.

A maa n ṣere tabi idije nipa ọrọ akọnilẹnu ki awọn eniyan le kọ sii nipa ede Yoruba ati fun idanilaraya ni.

Wọn tun maa n jẹ gbolohun alọ́niláhọ́n to jẹ pe o maa n gba ero ati ifarabalẹ ki eeyan to le gba a daadaa.