Yorùbá dùn lédè, sáré pé gbólóhùn yìí wò tóo bá dá ara rẹ lójú

Àkọlé fídíò, Yorùbá dùn lédè, sáré pé gbólóhùn yìí wò tóo bá dá ara rẹ lójú
Published

Ọ̀bọ ń gbọ́bọ g'ọ̀pẹ - O yá, ìwọ naa gbiyanju ẹ wo f'awọn ọmọ rẹ.

Ede Yoruba kun fun owe, aṣayan ọrọ, akanlo ede, afiwe ọrọ ati awọn ọrọ akọnilẹnu.

Ọrọ akọnilẹnu jẹ gbolohun ọrọ ti a to papọ ti a maa n sare sọọ ki eeyan le ṣe aṣiṣe tabi fihan pe o dangajia mimu ede Yoruba.

A maa n ṣere tabi idije nipa ọrọ akọnilẹnu ki awọn eniyan le kọ sii nipa ede Yoruba ati fun idanilaraya ni.

Wọn tun maa n jẹ gbolohun alọ́niláhọ́n to jẹ pe o maa n gba ero ati ifarabalẹ ki eeyan to le gba a daadaa.