Yoruba Culture: àṣà ìkínni ṣe pàtàkì nílẹ̀ Oodua
Ayọ abara tíntín ni Yoruba ka ọmọ tuntun sí.
Ẹbun ọfẹ ni ọmọ jẹ, ìran Yoruba si gbà pé ẹni tó ba wu Aṣẹda ni o le fun ni ọmọ lasiko to wu u.
Ni kete ti abiyamọ ba ti bi ìkókó si ilé ayé ni ẹbi, ara ati ojulumọ a ti wa maa ki wọn ku oriire alejo tuntun ni ọọdẹ wọn.
Nitori ki awọn ọmọde ati ọdọ Yoruba le ranti pataki ikinni nilẹ Oodua ni BBC Yoruba ṣe jade lọ beere bi a ti n ki ọlọmọ lọwọ awọn eniyan.
Oriṣii ikinni to wọpọ bii:
Ẹ ku ewu ọmo tuntun; Ẹ ku ọwọ lomi; Ayọ naa a kari; Olorun a wo o; Olorun a da a si, E ku ajabọ, O maa ni ọ̀wọ́ rere lẹ́yìn ati bẹẹ bẹẹ lọ ni a gbọ.
Ewu nla ni oṣu mẹsan an ti obinrin fi diwọ́-disẹ̀ sínú fi gbe oyun ikoko naa ki Edumare to sọ ọ kalẹ layọ.
Awọn eniyan ṣalaye kikun lori ohun to ṣokunfa awọn adura ati ikinni fun ọlọmọ tuntun daadaa.
- Àwọn kan fẹ́ da Naijiria rú torí ààbò tó mẹ́hẹ - Osinbajo gbarata
- Mo mọ̀ọ́mọ̀ dá €37,000 ti mo rí he padà ni -Ọmọ ogun Bashir
- Buhari yóò gbìyànjú láti lọ fún sáà kẹta
- Ìlú ò rẹ́rìn ín rárá, Alaafin Adeyemi III fárígá fún Buhari nínú lẹ́tà tuntun
- 'Kò sí ohun tó burú nínú bí Ajimobi ṣe dá Yewande tó pa ọkọ rẹ̀ sílẹ̀'