You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo ohun tí ojú ayàwòrán yìí ń rí nítorí ó jẹ́ obìrin
Awọn eeyan ilẹ Geẹsi maa n sọrọ kan sọ pe ohun ti okunrin le ṣe, obinrin le ṣe jubẹ lọ.
Amọ bi ọrọ ṣe ri kọ niyii fun Maryama Omar, to jẹ ayaworan obinrin lorilẹ-ede Somalia.
Akọṣẹmọṣẹ ni Maryama lootọ, amọ ọpọ igba to ba n ṣiṣẹ rẹ ni awọn eeyan, paapaa awọn okunrin, maa n dẹyẹ si lẹnu iṣẹ oojọ rẹ.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, akọṣẹmọṣẹ ni oun, oun si dantọ lẹnu iṣẹ naa, amọ idẹyẹsi naa ti pọ ju, ko si yẹ ko ri bẹẹ.
Maryama jẹ ọkan lara awọn oṣiṣẹ to n ya aworan fun Omar Filish, to jẹ gomina agbegbe to n gbe.
Maryama ni ẹnu iṣẹ ayaworan ni gomina ti ri oun ko to yan oun gẹgẹ bii ọkan lara awọn oṣisẹ rẹ.
Nurto Mohamed Adow, to jẹ oludasilẹ ile awọn ọmọ orukan kan sọ pe iwuri nla ni iṣẹ ti Maryama n ṣe jẹ fun oun, o si yẹ ki awọn eeyan Somalia dẹkun idẹyẹsi awọn obinrin ti wọn n ṣisẹ ti igbagbọ wa pe okunrin nikan lo wa fun.
Bo tilẹ jẹ pe ohun ti oju Maryama n ri lọwọ awọn okunrin ko tẹ ẹ lọrun, amọ ko si ohun to le ṣe si nitori ko si ofin to tako irufẹ iwa bẹẹ ni Somalia.
Wo fidio yii fun ẹkunrẹrẹ.