You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Ọjà kún 'nítorí ìdìbò ààrẹ'

Ẹ kaabọ si oju opo BBC Yoruba, wọnyi ni ohun ti awọn akoroyin wa to ti kalẹ kaakiri Naijiria n jabọ nipa ipalẹmọ idibo Aarẹ Naijiria.

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Ahmed Ambali and Busayo Akogun

  1. Kàkà k'éku mọ́ jẹ sèsé...àwọn jàndùkú dojú àpótí ìbò bolẹ̀ ní Lokoja

    Ọrọ di bo o lọ o ya n mi ni ibudo idibo Madabo niluu Lokoja lẹyin tawọn ọmọ gọnfe kan da oju apoti ibo bolẹ ti ọpọ si fẹsẹ fẹ.

  2. Kàkà k'éku mọ́ jẹ sèsé...àwọn jàndùkú dojú àpótí ìbò bolẹ̀ ní Lokoja

    Ọrọ di bo o lọ o ya n mi ni ibudo idibo Madabo niluu Lokoja lẹyin tawọn ọmọ gọnfe kan da oju apoti ibo bolẹ ti ọpọ si fẹsẹ fẹ.

  3. Wamuwamu ni awọn ọlọpaa duro ni ibudo idajọ yii, Ibudo idajọ ẹsun magomago lẹnu idibo ti Atiku pe Buhari ni Abuja

  4. Wo ibudo ti idajọ naa yoo ti waye loni laarin Atiku ati Buhari, Abuja ni idajọ yii yoo ti waye

  5. Wo awọn Adajọ ti yoo jẹ ki a mọ ẹni ti wọn yoo gbe ade le lori rẹ, Awọn adajọ to n ṣe igbẹjọ ẹsun idibo aarẹ Naijiria ni:

    Adajọ Abdul Aboki (Abuja Div.),

    Adajọ Joseph Ikyegh (Benin Div.),

    Adajọ Samuel Oseji (Lagos Div.)

    Adajọ Peter Ige (Abuja Div.)

    AdajọMohammed Garba

  6. Ẹ kaabọ si BBC Yorùbá, A o maa mu ohun gbogob to ba n ṣẹlẹ nibi eto idajọ igbẹjọ eto idibo aarẹ Naijiria

    Oni loni n jẹ ẹni a bẹ lọwẹ laarin Atiku Abubakar ti ẹgbẹ oṣelu PDP ati Muhammadu Buhari ti ẹgbẹ oṣelu APC

  7. Ẹseun pupọ!

    Nibi ni a o fi adagba eto rọ si laṣalẹ oni

    Lorukọ gbogbo awọn akẹgbẹ mi ti ati jọ ṣe akojọpọ iroyin wọn yi fun yin, a n ki yin pe ẹseun fun aduroti yin. E kan si wa lawọn ojuopo wa www.bbc.com/yoruba fun ẹkunrẹrẹ iroyin miran

  8. Ilé yá! Wo àwọn ọmọ Nàìjíríà tó ń lọ si ìlú wọn lọ dìbò

    Ọdun nikan kọ lo n gbe awọn ọmọ orilẹede Naijiria lọ si ilu wọn.

    Nitori idibo ọjọ satide, awọn olugbe ilu Abẹokuta kan pẹlu ti tẹkọleti lọ silu wọn lati lọ dibo

  9. Wo ibi tí gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun, Ibikunle Amosun yóò ti dìbò

    Ibudo idibo gomina ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun ni yii.

    Adugbo Itoko nilu Abẹokuta ni ibudo idibo naa wa.

  10. Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá mẹ́ta ni yóò mójútó ìdìbò l'Ekiti

    Komisona ọlọpaa mẹta ni yoo maa ṣe amojuto eto idibo ni Ipinle Ekiti.

    Amba Asuquo to jẹ komisona to n ṣakoso ipinle naa tẹlẹ, ati komisona mejì mii ti ọkan lara wọn jẹ Posi Ajuwon ti yoo maa ṣe amojuto agbegbe Ikere ati akegbe rẹ ti yoo maa moju to agbegbe Ido osi.

    Alukoro ile iṣe olopaa ipinle Ekiti Ogbeni Ikechukwu lọ fidi oro naa mulẹ fun BBC.

  11. Kò sí ìfòyà fáwọn olùdìbò lọ́jọ́ àbámẹ́ta-Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá nípínlẹ̀ Ọ̀yọ́

    Oju gbogbo yoo wa lara ipinlẹ Ọyọ lasiko idibo ọjọ abamẹta, ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe ko si ifoya nitori awọn ọlọpaa ti gbaradi pẹlu awọn ọlọpaa to wọ aṣọ atawọn ọtẹlẹmuyẹ.

  12. Ǹjẹ́ o mọ ibi tí ààrẹ orílẹ̀èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ yóò ti dìbò?

    Nibi yii ni aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ, Oluṣẹgun Ọbasanjọ yoo ti dibo ni ọjọ abamẹta.

    Agbo ile olushomi ni Shokori, ni ilu Abẹokuta ni orukọ ibẹ.

    Ẹyin naa lee fi orukọ ibudo tiyin naa sọwọ si oju opo facebook wa ni bbcnewsyoruba

  13. Àwọn olórí máa ń rò pé ọ̀dẹ̀ ni aráàlú-Fayose, Fayose tún sọrọ lori ọrọ apilẹkọ ti aarẹ ba awọn ọmọ Naijiria sọ ni ọjọbọ

    Gomina ana nipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayose ṣalaye fun BBC News Yoruba pe akoko to fun awọn oludibo lati mọ pe awọn ni agbara ju oloṣelu kankan lọ.

    O ni aṣiṣe ni fun awọn olori lati maa ro pe ọdẹ ni araalu.

    Bakan naa lo sọrọ lori ọrọ apilẹkọ ti aarẹ ba awọn ọmọ Naijiria sọ ni ọjọbọ

    ��

  14. Ìjọba àpapọ̀ ti ẹnubodè ẹnubodè Nàìjíríà nítorí ìdìbò Sátidé, Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá pẹ́lú ti kéde pé kò ní síìgbòkègbodò ọkọ̀ lọ́jọ́ àbámẹ́ta

    Minisita fọrọ abẹle, Abdulrahaman Dambazau, to kede ọrọ yii ni igbesẹ naa wa lati rii pe ko si wọle wọde awọn ajoji to lee fẹ wa dibo tabi da wahala silẹ lasiko idibo naa.

    Bakan naam, ileeṣẹ ọlọpaa ti fofin de igbokegbodo ọkọ ni ọjọ abamẹta laaarin agogo mẹfa owurọ si mẹfa irọlẹ.

    Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Frank Mba ni Ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Mohammed Adamu pa aṣẹ yii lati dena awọn janduku to lee fẹ ji apoti ibo gbe.

  15. Ọjà kún nílùú Akurẹ 'nítorí ìdìbò ààrẹ'

    Fọ-fọ-fọ ni awọn ọja kun ni ilu Akurẹ nibi ti awọn eeyan ti n ra ohun jijẹ silẹ ṣaaju idibo ọjọ abamẹta.

    Akroyin BBC News to wa si Oja oba ni ilu Akurẹ ṣalaye pe awọn wa lati ri wi pe awon ra ounje si ile saaju idibo to n bo lọjọ abamẹta.

    Bakan naa ni awon ọlọja lọja naa pẹlu pe fun alaafia lasiko idibo ati leyin idibo.

  16. Àríyànjiyàn lórí òṣìṣẹ́ tí yóò mójútó ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Kwara

    Ariyanjiyan loriṣiriṣi lo ti n waye baye laarin awọn to fẹ ṣiṣẹ alamojuto idibo nipinlẹ Kwara.

    Ohun ti wọn sọ fun BBC News Yoruba ni pe lẹyin idanilẹkọ ọjọ mẹta, orukọ awọn ti ajọ INEC gbe sita n mu ifunra lọwọ.

  17. EFCC ṣèlérí ìjìyà fáwọn ràbòràbò àti tàbòtàbò

    Ajọ EFCC ti sọ pe ijiya n bẹ fun ẹnikẹni ti ọwọ ba ba ti o n ta ibo tabi ra ibo lasiko idibo ọjọ abamẹta.

    Ajọ naa tilẹ ti gbe nọmba ibanisọrọ ti awọn araalu lee pe si ti wọn ba kẹẹfin ẹnikẹni ti o ba n ta ibo tabi ra ibo.

    Awọn nọmba naa niyi:

    • 07083470063
    • 09064116750
  18. Àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀ lórí ìrètí wọn nípa ìdìbò 2019

    Lati Eko de Kwara, Maiduguri de Rivers ni awọn ọmọ Naijiria ti n sọ ero wọn lori ohun ti wọn fẹ nipasẹ idibo apapọ ọdun 2019.

  19. Wọn ti bẹrẹ si ni pin nnkan elo idibo ni Ado Ekiti

    Lẹyin orẹyin ajọ eleto idibo Inec nipinlẹ Ekiti ti bẹrẹ si ni pin awọn nnkan elo idibo ni ilu Ado Ekiti.

    Nigba ti akọroyin wa de ibudo ile ifowopamọ agba, niṣe ni wọn ti n ko awọn nnkan elo naa ti wọn si ti n yanju wọn saaju pinpin wọn lọ si agbegbe ibi ti wọn yoo ti lo wọn

  20. Ẹ jáde lọ dìbò pẹ̀lú ìfẹ́- Ọọ̀ni Ilé ifẹ, Ọọni Ogunwusi ni idibo ṣe pataki fun ọjọ ọla Naijiria

    Ọọni ile ifẹ, Adeyẹye Ogunwusi ti rọ awọn ọmọ Naijiria lati jade lọ dibo ni ọjọ abamẹta.

    Ninu ọrọ ti Ọbalaye naa fi sita ni Ile Oodua tii ṣe aafin rẹ ni Ile Ifẹ, o ni bi awọn ọmọ Naijiria, paapaajulọ awọn ọdọ ṣe tu yaya lọ ṣe ayajọ ololufẹ ni ki wọn mu irufẹ ifẹ bẹẹ dani lọ si ibudo idibo lai fa wahala.

    O ni ẹbun ifẹ ti awọn ọmọ orilẹede Naijiria lee fun orilẹede yii ni lati yan awọn olori ti yoo mu idagbasoke ba orilẹede Naijiria sipo