Wọ́n ti búrawọlé fún obìnrin méje tí wọ́n dìbò yàn gẹ́gẹ́ bíi gómìnà ní Kenya

Oríṣun àwòrán, Kenyans.co.ke
Wọn ti burawọle fun awọn obinrin meje gẹgẹ bii gomina lẹyin eto idibo sipo gomina to kọja lorilẹ-ede Kenya ninu eyii ti wọn ti dibo yan gomina marundinlaadọta lapapọ.
Eto idibo naa ti fun awọn obinrin lẹnu lawujọ lẹyii to jẹ pe ṣaaju idibo naa, obinrin mẹta pere lo wa ni ipo to ṣe pataki lorilẹ-de naa.
Awọn gomina lo wa nidi eto iṣuna ni Kenya, lara ojuṣe wọn si ni lati bojuto awọn agbegbe ti wọn n dari.
Ko din ni obinrin ogun to dije du ipo lawọn ẹkun ni Kenya ki awọn meje yii to wọle.
Bo tilẹ jẹ pe obinrin lo fẹẹ ko idaji ninu awọn oludibo to forukọsilẹ ni Kenya, iwọnba obinrin perete lo di ipo oṣelu mu.
Adajọ agba akọkọ to jẹ obinrin, Martha Koome, ti lo yan awọn adajọ marundinlaadọta to ṣe eto iburawọle awọn gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ọhun.
Orukọ awọn obinrin ti wọn burawọle fun gẹgẹ bii gominaree
- Fatuma Achani - Kwale County
- Susan Kihika- Nakuru County
- Cecily Mbarire- Embu County
- Kawira Mwangaza - Meru County
- Wavinya Ndeti- Machakos County
- Anne Waiguru - Kirinyaga County
- Gladys Wanga- Homa Bay County
Mo ti ṣiṣẹ ọmọ ọdọ ri
Ẹwẹ, ọkan lara awọn gomina obinrin tuntun naa, Kawira Mwangaza, ti sọ pe oun ti ṣiṣẹ ọmọ ọdọ ri ki ọna to la fun oun.
O ṣalaye fun BBC pe oun ko sọ ireti nu ninu gbogbo awọn ohun ti oun n la kọja lọdun naa lọhun.
Koda, o ni oun kuro nile ẹkọ lasiko ti oun wa nile ẹkọ girama, ti oun si ṣiṣẹ ọmọ ọdọ lọna atijẹ, amọ adun lo pada gbẹyin ewuro oun.























