Ẹ wo àwọn nǹkan tí Tinubu ń fi owó tó ń wọlé sápò ìjọba ṣe ní Naijiria

Aworan aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ aarẹ ti ṣalaye bi ijọba Aarẹ Bola Tinubu ṣe n nawo to n wọle sapo ijọba apapọ.

Ileeṣẹ aarẹ ni oniruuru eto ti yoo fun araalu ni ireti ọtun ni ijọba APC to wa lode n nawo le lori lọwọ yii.

Oludamọran pataki fun aarẹ lori ọrọ iroyin ati ibaraẹnisọrọ, Sunday Dare, lo fidi ọrọ yii mulẹ loju opo X rẹ.

Dare ṣe atupalẹ awọn nnkan ti ijọba n ṣe pẹlu owo to n wọle, o ni oriṣiiriṣii eto ti yoo ṣe anfaani fun araalu ni ijọba n nawo le lori.

Alaye yii waye lẹyin ti ọpọ eeyan papaa julọ awọn adari ẹgbẹ oṣelu alatako n kọminu lori gbese ti Naijiria ti jẹ labẹ ìjọba Tinubu.

Gẹgẹ bi Dare ṣe ṣalaye, lara awọn eto ti ijọba Tinubu n nawo le lori julọ ni eto ẹyawo ati owo iranwọ fawọn olokowo alabọde to le ni 900,000 to fi mọ awọn to n pese nnkan ti araalu n lo bakan naa.

Oludamọran aarẹ ni ijọba gbe igbesẹ yii lati ri pe awọn olokowo kekeke n ṣiṣẹ eyi ti yoo mu adinku ba ìṣòro airiṣẹṣe ni Naijiria.

Dare ni ijọba gbagbọ pe ṣiṣe atilẹyin fawọn olokowo kekeke yii yoo mu adinku ba oṣi ati iṣẹ to n ba ọpọ eeyan finra, yoo si tun mu idagbasoke wa.

Eto mii ti ijọba tun n nawo le lori ẹka igbokegbodo ọkọ ati ṣiṣe ọna kaakiri orilẹede Naijiria.

Ọgbẹni Dare ṣalaye pe o le ni ọna 440 ti ijọba n ṣe lọwọ kaakiri orilẹede Naijiria eyi to to kilomita 2,700 ti yoo jẹ ki eto okowo gberu sii.

O ni awọn ọna yìí ti so oniruuru gbagede okowo pọ, eyi ti yoo mu adinku ba ọwọngogo nnkan ti yoo si tun fawọn olokowo lanfaani lati le maa ra ọja kaakiri.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹka eto ẹkọ náà ko gbẹyin ninu awọn nnkan ti ijọba n nawo le lori papaa julọ eto ẹyawo NELFUND fáwọn akẹkọọ ile ẹkọ giga táwọn akẹkọọ bíi 500,000 kaakiri awọn ile ẹkọ fasiti at'awọn ile ẹkọ giga mii ni Naijiria ti janfaani rẹ.

Oludamọran aarẹ ni ọgọọrọ akẹkọọ ni eto yii ti se iranwọ fún lati jẹki wọn janfaani eto ẹkọ to ye koororo pẹlu owo ti wọn ko ni da pada ni kiakia.

Ileeṣẹ aarẹ ni ijọba ṣe agbekalẹ eto ẹyawo NELFUND lati fopin si ìṣòro airowo ile iwe san t'awọn akẹkọọ ti obi wọn ko rọwọ họri maa n koju.

Nnkan mii gboogi ti ijọba Tinubu tun n nawo le lori ni imuṣẹ ati sisan #70,000 gẹgẹ bii owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.

Ọgbẹni Dare ṣalaye pe alekun owo oṣu ti ijọba Tinubu ṣe ti ro awọn oṣiṣẹ lagbara lati gbe igbe aye to dara pẹlu ọwọngogo to gbòde.

Oludamọran aarẹ ni ijọba apapọ n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ijọba ìpínlẹ̀ àti ti ibilẹ lati le ri pe awọn oṣiṣẹ wọn naa jẹ anfaani yii.

Bakan naa ni o tun sọ pe awọn oniṣẹ aladani papaa yoo ṣe alekun owo oṣu fawọn oṣiṣẹ wọn, eyi ti yoo si jẹ ki ọrọ aje Naijiria gberu sii.