Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Published

Njẹ ẹ ti gbọ?

Olofofo o tun de! Ki la ri gbọ lọtẹ yii?

Ṣe iwọ mọ pe orilẹ ede Naijiria ti ni aṣọ ẹgbẹjọda

Ẹhn ẹhn ṣe loootọ?

Lana ode yii ni aya aarẹ Naijiria, Remi Tinubu ṣafilọlẹ aṣọ naa

O ni aṣọ naa wa fun ipolongo iṣọkan ni Naijiria

Aya aarẹ ni aṣọ naa ni gbogbo ọmọ Naijiria yoo wọ fun ayajọ ominira Naijiria gba ominira ti yoo waye lọjọ Kiini oṣu Kẹwaa

Omiran tun re o

Ewo tun ni?

Ṣe o tumọ pe gbigbagbe nnkan ni anfani ati oore ninu

O tun gbe de o

Iwadii ijinlẹ kan sọ pe bi eeyan ba ṣe n gbagbe nnkan ni ọkan eeyan yoo maa fuyẹ si

Kan si oju opo bbc.com/yoruba fun ẹkunrẹrẹ alaye kikun nipa awọn anfani naa

Ẹṣọ aabo ara ẹni labo ilu, NSCDC ti nawọ gan ọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelọgọta, Nnanna Micheal

Fẹsun wi pe o ni ile iṣẹ ti wọn ti n ta ọmọ ni ilu Aba

NSCDC ni oloyun meji ni wọn gba itusilẹ kuro ni akata rẹ