Ìgbẹ́jọ́ kò le parí láì jẹ́ pé ẹni tó ri ẹ̀rọ CCTV sílẹ̀ Princess yọjú sílé ẹjọ́ - Baba Ijesha

Published

Ilé ẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ tí wọ́n fi kan Baba Ijesha ti mú ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Keje, ọdún 2022 gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí yóò gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹ̀sùn náà.

Ní ọjọ́ Ajé ọjọ́ Kẹfa, oṣù Kẹfa ọdún 2022 ni ìgbẹ́jọ́ Olarenwaju Omiyinka ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Baba Ijesha ń tẹ̀síwájú lórí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ tó ń jẹ́ ní ilé ẹjọ́ tó ń rí sí àwọn àkànṣe ẹjọ́ ní Ikeja, ìpínlẹ̀ Eko.

Agbẹjọ́rò Baba Ijesha, Dada Awosika níbi ìgbẹ́jọ́ náà sọ fún ilé ẹjọ́ wí pé ilé ẹjọ́ nílò láti se atungbeyẹwo ọ̀rọ̀ ọjọ́ orí ọmọ tí wọ́n fi ẹ̀sùn rẹ̀ kan òun, wí pé òun bá lòpọ̀ kìí ṣe òótọ́.

Ó ní kò yẹ kí wọ́n gbá fídíò inú CCTV náà wọlé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí.

Níbi ìgbẹ́jọ́ tó kẹ́yìn ni Baba Ijesha ti sọ fún ilé ẹjọ́ wí pé orí ìtàgé ni òun àti Princess jọ ń ṣe kí wọ́n tó sọ ọ̀rọ̀ àná di báàmì mọ́ òun lọ́wọ́.

Ẹ̀wẹ̀, agbẹjọ́rò ìjọba ní tirẹ̀ tako gbogbo ohun tí akẹgbẹ́ rẹ̀ sọ̀ yìí bó ṣe rán ilé ẹjọ́ létí wí pé ẹlẹ́rìí tí àwọn Baba Ijesha gbé wá sílé ẹjọ́ ìyẹn Lawrence Ayeni fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé kò ṣeéṣe kí ènìyàn ṣe àtúnṣe sí fọ́nrán CCTV.

Lẹ́yìn atótónu gbogbo àwọn agbẹjọ́rò méjéèjì, adájọ́ Oluwatoyin Taiwo ti wá sún ìdájọ́ rẹ̀ sí ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Keje, ọdún 2022.