You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìjọba àpapọ̀ dáwọ́ iṣẹ́ dúró ní òpópónà márosẹ̀ Eko sí Ibadan
Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti dawọ isẹ duro loju ọna opopona morosẹ Eko si Ibadan lati pe ọna to lọ gerege fun awọn arin rinajo fun pọpọsinsin ọdun ileya ti yoo waye lọsẹ yii.
Ẹka ijọba to n risi isẹ ati ile gbe, ninu atẹjade ti asoju wọn nipinlẹ Eko, Arabinrin Olukayode Kesha fi sọwọ si awọn akọroyin lọjọ Aje pe awọn yoo dawọ isẹ duro lati ọjọ Isẹgun, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹfa di ọjọ Aiku, ọjọ keji oṣu keje
Gẹgẹ bii o se sọ, "Igbesẹ yii ni a gbe lati fi dẹkun sunkẹrẹ fakẹrẹ to wa loju ọna opopna marosẹ Eko si Shagamu lasiko pọpọsinsin ọdun ileya, ti a si ti rọ awọn ẹsọ oju popo lati se amojuto igbokegbodo ọkọ lasiko ọdun."
"Isẹ yoo pasa lọjọ Aje, ọjọ kẹta, oṣu kej, ọdun 2023.
"Eyi ni lati fi aye silẹ fun awọn arinrin ajo lati rin lai si idaduro lasiko ọdun ileya.
"A gba gbogbo awọn arin rinajo niyanju lati tẹle gbogbo ofin ti awọn ẹsọ oju popo fi lade lasiko yii."