Senator Olujimi on Yoruba Nation: Ẹ wo Sẹ́nétọ̀ obìnrin tó gbàgbọ́ nínú àtúntò Nàìjíríà àti ìjà fún ìyapa Nàìjíríà

Published

"Olóore ni mo jẹ́ sí Fayose la ṣe le ṣiṣẹ papọ, ko si ija laarin wa".

Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun Guusu Ekiti nile igbimọ aṣofin, Abiodun Christine Olujimi ti ni bo pẹboya, ko si igba ti awọn adari Naijiria ko ni gba si awn to n ja fun ẹtọ wọn lẹnu.

Bakan naa lo ṣalaye idi to fi dara ki awọn obinrin kopa ninu oṣelu.

O fi ara rẹ ṣe apẹrẹ gẹgẹ bo ṣe n ṣoju ẹkun kan l'Ekiti to jẹ ilu baba rẹ.

"Too ba fẹ dupo, wọn a ni ilu ọkọ ẹ ni koo lọ, boo ba tun lọ si ilu ara rẹ, awọn naa a ni ṣebi o lọkọ. Ọpẹlọpẹ Ọlọrun ni mo ṣe wa ni ipo ti mo wa yii".

Arabinrin Olujimi tun ba BBC Yoruba sọrọ lori awọn to n ja fun Yoruba Nation ati ipo ti Naijiria wa lọwọlọwọ.

Àtúntò Nàìjíríà ni mo tò fún o, ìdí tí ẹ ṣe ní láti gbọ́ sí àwọn tó ń jà fún Yoruba Nation lẹ́nu rèé - Sẹnetọ Olujimi

O ni ilu le gan lasiko ti a wa yii ti gbogbo eniyan si n duro de asiko idibo to n bọ lati ṣe ipinnu to yatọ ti yoo mu aye wọn lọ siwaju.