You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ó kéré tán, ó yẹ kí èèyàn máa pààrọ̀ ìfọyín rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan láàrín oṣù mẹ́ta - Dókítà eyín
Dokita kan to n ṣe itọju eyin, Modupe Oyetade ti sọ pe ti eeyan ko ba tọju eyin rẹ daadaa, o le yọri si aisan ọkan.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, Oyetade ṣalaye pe aisan kan ti wọn n pe ni akokoro le pa eeyan lara.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn kokoro to n gbe ninu ẹnu eeyan ti ko si kuro nibẹ le ṣakoba fun ọkan eeyan.
Dokiya naa ṣalaye siwaju si pe awọn kooro eyin ọhun tun le ṣakoba fun alaboyun.
- Ọ̀lọ́pàá 34,587 níjọba àpapọ̀ ń rán lọ Anambra láti kojú agbébọn tó bá gbémú
- "Á fimú Odunlade Adekola dánrin tó bá kọ̀ láti ṣe àtúnṣe lórí títàbùkù ẹ̀sìn Islam nínú fíìmù rẹ̀"
- Wo aṣòfin àpapọ̀ tó fẹ́ káwọn káfíńtà àti dẹ́rẹ́ba ọlọ́kọ̀ èrò má san owó orí, Ó ní owó kékéré kó ni wọ́n rí
- Buhari, wá nǹkan ṣe sí àwọn agbésùmọ̀mí àti agbébọn tó ń pẹ̀ka bí ìrókò-Afenifere
- Iyorchia Ayu di alága tuntun fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP
- A pinu láti sinmi díẹ̀ lẹ́yìn ìgbeyàwó ká tó bímọ àmọ́ ó yíwọ́ - Wumi Toriola
O ni “Ti awọn kokoro ba wa ninu eyin, ti wọn ko si kuro nibẹ, ti wọn korajọ sinu erigi, o le fa aisan ọkan fun eeyan.”
“To ba jẹ obinrin to loyun ni, awọn kokoro naa a lọ si ibi ti ile ọmọ rẹ wa, wọn a jẹ ki o bi ọmọ ti ko tii to bi.”
Oyetade sọ siwaju si pe “Ẹlẹkẹta, awọn kokoro naa le lọ si ibi nnkan ọmọkunrin ti wọn ti n pese aatọ, wọn a dẹ lọ fa adinku ba ipa irufẹ ọkunrin bẹẹ lati le fun obinrin loyun lasiko ibalopọ.”
Lẹyi naa lo gba awọn eeyan nimọran lati dẹkun lilo awọn nnkan to le pa ẹyin wọn lara lati fọ ẹnu bii omi batiri ati bẹẹ lọ.
Niti awọn to maa n lọ ṣe èjí atọwọda nitori ẹwa, awọn to fẹran lati maa lo igi itayin fun wakati pipẹ atawọn to fẹran lati maa bo eyin wọn ko le funfun daadaa lai kọkọ kan si dokita wọn, Oyetade sọ pe ewu nla ni wọn n fun ilera ara wọn.
Ẹkunrẹrẹ ohun ti dokita eyin naa sọ wa ninu fidio yii.