Ilé wó lu Bisi, ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kú, wọ́n gé ẹsẹ̀ rẹ̀ tó ń jẹrà, inú ìrora ló wà ṣùgbọ́n Dókítà tún ń sọ pé...

Published

Awọn agba bọ wọn ni bi a ba n wa ohun ti a o jẹ, ki a maa pade ohun ti yoo jẹ wa.

Ọrọ Abilekọ Bisi Ajayi jẹ eyi ti yoo gbomi loju ọpọlọpọ.

Bisi, jẹ oniṣowo kekeke to si jẹ wi pe inu ere to n ri lori owo rẹ yii lo fi n gbọ bukata ẹbi rẹ; iyẹn ohun, ọkọ ati ọmọ mẹrin ti wọn bi.

Amọṣa, lati nnkan bi oṣu meji bayii ni Bisi ti wa nile iwosan nibi ti ko le rin, koda ko lee yi ara pada funrarẹ lori ibusun to wa.

Nigba to n ṣalaye bi irinajo aye rẹ ṣe jẹ, Abilekọ Bisi Ajayi ni oun jade gẹgẹ bi iṣe rẹ lati wa ohun ti oun atawọn ọmọ oun yoo jẹ ni ọjọ kẹfa oṣu kẹfa ọdun 2021 ni ile kan fi wo lu oun ati ọmọ ti oun pọn si ẹyin, loju ẹsẹ ni ọmọ to pọn jade laye ti wọn si gbe oun tikalara digbadigba lọ si ato egungun lọna ti ibilẹ fun itọju.

Amọṣa, o ni lẹyin asiko diẹ ni ẹsẹ naa bẹrẹ si nii run ti wọn si ni lati gee nileewosan.

Nigba ti o ṣi n ba iyipada ọtun to de ba aye rẹ yii finra ni wọn ba tun sọ fun un pe nnkan ti ṣe egungun ẹyin rẹ ati pe o nilo iṣẹ abẹ fun atunto rẹ.