You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Oriire Oyo Farmers: Bí àwọn Darandaran ṣe ba okò opó kan jẹ́
Awọn agbẹ ijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Oyo n kigbe sita lorii ikọlu lemọlemọ ti awọn darandaran n ṣe lori awọn oko wọn bẹẹ iṣẹ oko yii nikan ni owo ti wọn n ṣe to wọpọ nibẹ.
Tẹkun tẹkun ni awọn agbẹ naa to fi mọ obinrin, ọkunrin atawọn ọdọ wọn fi ba BBC Yoruba sọrọ ti wọn si n fi awọn ere oko tawọn akọluni darandaran da ẹmi wọn legbodo han.
Koda wọn ni o la iku lọ fun awọn kan lara awọn lasiko ti ọrọ di ogun laarin wọn ti awọn to farapa naa si wa nibẹ.
"Gbogbo nkan mi ni wọn ti bajẹ patapata, awọn ọmọ wa si wa nile ẹkọ ti a o ri nkankan fi tọ wọn".
- Wo ọ̀rọ̀ Fani-Kayode sí akọ̀ròyìn "blog" tó ní lílù ìyàwó rẹ̀ bíi bàrà ló mú wọn túká
- Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọbalayé ní kò yàtọ̀ sí èèyàn lásán - Elebuibon
- Ohun méje tí Jimoh Aliu fi yàtọ̀ lágbo tíátà
- Ikorodu Bois fí àwàdà bọ àwòrán àwọn ọmọ Otedola, ẹ wo ará tí wọ́n dá
- Ọdún mọ́kànlá rèé témi àti ọkọ mi bẹ̀rẹ̀ ìfẹ́ láti ilé ẹ̀kọ́ girama - Bukunmi Oluwasina
Ọkan lara wọn ni oun n sọ fun wọn pe oun o pa ara oun ni ti wọn si n bẹ ẹ.
Awọn araalu ni o ti su awọn pẹlu iṣoro awọn Bororo darandaran ti awọn si ti lọ fi ẹjọ sun ọlọpaa lọpọlọpọ igba.
Baba ka ni ilẹ oko bii aadọta eeka ni oun gbin ẹgẹ nlannla si toun si ro gbogbo aarin poro to mọ tonitoni amọ nigba ti oun fi pada lọ bẹẹ wo gbogbo wew ti mọ feee, "ẹkun ni mo ba wale.
Ẹwẹ Umar Babuga Yayi Guruma to jẹ Seriki awọn Fulani ni ilu Ogbomoso naa fesi fun BBC Yoruba ni iha titi rẹ toun naa.