You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Schools Resumption: Ohun tó yẹ kí o mọ̀ b'áwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣé fẹ́ wọlé padà ní Ogun,Èkó àtàwọn ìpínlẹ̀ míì
Ni ibamu pẹlu aṣẹ ileeṣẹ eto Eko ni ipinlẹ Eko, Ogun ati Kwara awọn akẹkọọ yoo pada sileewe lọjọ Iṣẹgun tii ṣe ọjọ Kẹrin oṣu Kẹjọ ọdun 2020.
Ṣaaju ni ijọba apapọ Naijiria naa ti kede pe ki awọn akẹkọọ ti yoo kọ idanwo aṣekagba jakejado Naijiria pada sile ẹkọ ni igbaradi de idanwo wọn.
Ninu awọn ipinlẹ ti yoo wọle pada ṣẹnu ẹkọ lọjọ Aje ni ipinlẹ Cross Rivers wa.
Ipinlẹ Oyo ti kọkọ fi orukọ silẹ gẹgẹ bi ipinlẹ to bẹrẹ ẹkọ pada loṣu Keje.
Ni ipinlẹ Eko ati ipinlẹ Ogun awọn akẹkọọ ti yoo kọ idanwo aṣekagba SSCE ti wọn n wa lati ile ati awọn eyi to n gbe ni ileewe ni wọn ti ni ki wọn pada sẹnu Eko.
Awọn eleto ẹko ti kede awọn ilana kan kalẹ fawọn akẹkọọ eyi ti yoo mojuto idaabo wọn lọwọ ajakalẹ arun Covid-19.
Yatọ si lilo ibomu ati fifọ ọwọ wọn ki wọn to wọ kilasi, awọn ipinlẹ bi Ogun ti paṣẹ ki gbogbo awọn akẹkọọ mu iwe ẹri ayẹwo wa to ṣafihan pe wọn ko ni arun Covid-19 lara.
Ọrọ owo ayẹwo yi ti n mu iriwisi ọtọọtọ wa paapa ni ipinlẹ Ogun nibi ti awọn obi kan ti n faraya pe owo ayẹwo yi ko rọrun fawọn la ti san.
Ninu atẹjade kan, olubadamọran Gomina lori eto ẹkọ alakọbẹrẹ ati ileewe Girama ni ipinlẹ Ogun, arabinbrin Ronke Soyombo ni awọn gbe igbesẹ ayẹwo yi lati dena itankalẹ arun Covid-19.
O ni awọn ilana to rọ mọ ayewo yi ni pe ijọba ni yoo san owo ayẹwo f'awọn akẹkọọ ileewe ijọba.
Ni tawọn ile ẹkọ to ni akẹkọọ to n gbe ileewe ,o ni o di dandan ki wọn mu esi ayẹwo yi wa.
Soyombo sọ pe ijọba yoo ṣe ẹdinwo fawọn akẹkọọ ileewe aladani lori owo ayẹwo yi sugbọn ẹni to ba fẹ ṣe ayẹwo lọwọ ara rẹ ni lati ṣe lawọn aaye ti ajọ to n gbogun ti arun ni Naijiria NCDC buwọlu.
BBC ko ribi fidi mulẹ iye ti owo ayẹwo yi jẹ gaan ṣugbọn awọn obi kan to ba awọn ile iṣẹ iroyin Naijiria sọrọ lori iṣẹlẹ yi ni awọn ko ni le san ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn naira ti ijọba fẹ gba fun ayẹwo yi.
Awọn ipinlẹ miran bi Enugu,Gombe ati Rivers ko ti kede ọjọ tawọn akẹkọọ wọn yoo wọle ti ọpọ awọn onwoye si n beere pe ṣe awọn ileekọ wọn yi ti gbaradi kalẹ pẹlu gbogbo eto to yẹ ṣaaju iwọle awọn akẹkọọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Akeredolu, aya àti ẹbí rẹ̀ ló ń ṣèjọba ni mo ṣe fipò sílẹ̀ - Akọ̀wé ìjọba tẹ́lẹ̀ l‘Ondo
- Àlàyé rèé lórí ìdí tí Magu àti awọn alága EFCC míràn ṣe bá ìtìjú kúrò nípò
- Àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ń bèèrè owó lọ́wọ́ àwọn Alfa lórí ìsìnkú ẹni tó pokùnso
- Hushpuppi di gbajúmọ̀ ẹlẹ́wọ̀n tó ní nọ́ńbà l‘Amẹrika, orúkọ̀ rẹ̀ wà lórí ayélujára
- Nǹkan tí ojú rí rè é bí pápákọ̀ òfurufú ṣe di ṣíṣí padà ní Nàìjíríà
- Ṣé lóòtọ́ ni Lateef Adedimeji àti Adebimpe Oyebade ṣe ìgbéyàwó?
- Kòṣẹlẹ̀rí ni Hajj ọdún 2020, wo ìyàtọ̀ tó wà nínú rẹ̀ sí ti tẹ́lẹ̀
Inú wa kò dùn pé Seyi Makinde ṣílẹ̀kùn iléẹ̀kọ́ padà l'Oyo - Àwọn òbí
Awọn obi kan tako bi ijọba Seyi makinde se si ileewe pada nipinlẹ Ọyọ.
Bi o tilẹ jẹ pe awọn akẹkọọ to wa ni kilaasi akẹkọjade nikan lo wọle pada, sibẹ awọn obin to ba BBC Yoruba sọrọ ni akoko ko ti to lati silẹkun ileewe pada.
Awọn obi naa, lasiko ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ ni, ki lo de tawọn akẹkọọ alakọbẹrẹ ati girama fi wọle pada sile iwe, nigba tawọn ẹgbọn wọn to wa ni fasiti ati Poly si wa nile.
Awọn Olukọ to ba ikọ iroyin wa sọrọ naa tun salaye gbogbo awọn igbesẹ ti wọn n gbe, lati ri daju pe awọn akẹkọọ naa tẹle awọn ofin ati ilana to rọ mọ idena arun Coronavirus.