Niyi Akinmolayan tó ṣe fíìmu àwòrán-dèèyàn 'Cartoon' nípa COVID-19 tó la ayé já ní Nàìjíríà leè lo sinimá fún ìgbélékè àṣà

Published

Lara awọn iṣoro to yọju fun awọn orilede, lasiko ajakal arun coronavirus yii ni ọna lati ṣalaye rẹ fun awọn ọmọde.

Ọpọlọpọ obi lo si ti ni lati pariwo titi lọna ati ṣalaye fun awọn ọmọ wọn idi ti wọn ko ni lee fi l si ile iwe tabi lba awọn rẹ wọn ṣere, ṣugbọn sibẹ ti ko dabi eyi to w eti awọn ọmọ wọn.

Amọṣa, ilumọọka ayaworan sinima kan, Ọgbẹni Niyi Akinmọlayan ti oun pẹlu ni iriri yii gbe fidio aworan-deeyan kan ti a mọ si Cartoon jade eleyi to ti mu ki alaye naa rọrun fun awn obi lai ni sọ r kan ṣoṣo.

Ọgbẹni Akinmọlayan ba BBC News Yoruba sọrọ lori idi to fi lo ọna yii.