N6 mílíọ̀nù ni mo pín fún àwọn òṣìṣẹ̀ OSOPADEC nìkan nínú N30mílíọ̀nù tí gómìnà Akeredolu ní kí n fi ṣètò ìdẹ̀rùn -Alága Àjọ OSOPADEC

Published

Ọgbọn miliọnu ti Akeredolu gbe silẹ fun ajọ idagbasoke awọn agbegbe ipọnpo ni ipinlẹ Ondo, OSOPADEC fun imayedẹrun awọn ara ẹsẹ odo nibẹ ti da ariyanjiyan silẹ bayii.

Awọn ọdọ, paapaajulọ awọn ọdọ agbebọn to ti ronupiwada lagbegbe naa n fi ẹsun kan alaga igbimọ ajọ OSOPADEC pe miliọnu mẹta pere lo na ninu ọgbọn miliọnu ti gomina ipinlẹ naa, Rotimi Akeredolu gbe kalẹ fun imayedẹrun fun awọn eeyan ẹsẹ odo ni ipinlẹ naa.

Amọṣa alaga igbimọ iṣakoso ajọ OSOPADEC ni ipinlẹ Ondo Gbenga Edema ṣalaye pe lootọ ni gomina Akeredolu gbe Ọgbọn miliọnu naira kalẹ, ṣugbọn irọ ni pe miliọnu mẹta pere ni oun ri naa nibẹ.

Bo ṣe naa gbogbo owo yii lo la kalẹ ninu fido oke yii lasiko ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba.