Lekki Toll gate: Àwọn awakọ̀ Lekki sọ èrò wọn nípa ìrìnà ọ̀fẹ́ ní ibodè Lekki

Published

Àwọn awakọ̀ to n rin loju ọ̀na marosẹ Lekki si Ajah nilu Eko ti kan saara si gomina Babajide Sanwo-Olu lori bo se si ẹnu bode ọna naa silẹ ni Ọjọbọ.

Nigba ti wọn ba BBC Yoruba sọrọ, awọn araalu naa ni o wu awọn kijọba jẹ ki awọn maa rin opopona ọhun lọfẹ ni ojoojumọ.

Wọn salaye pe eyi too mu ki sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ dopin loju ọna yii, ti ara yoo si rọ awọn eeyan to n gbe ni Lekki-Ajah.