Ondo Election 2020: Àwọn òfin àjọ INEC l'Ondo fún ìdìbò ọjọ́ Sátidé

Published

Ọga agba ajọ INEC ni ipinlẹ Ondo, Rufus Akeju ni ireti awọn lọdọ awọn oludibo ti yatọ lọtẹ yii si ti tẹlẹ o torinaa ohun ti wọn yoo mu wa lati dibo ju kaadi idibo wọn nikan lọ.

O tun mẹnu ba ọrọ ẹrọ to n ṣayẹwo kaadi to jona ni ipinlẹ Ondo nigba diẹ sẹyin ki asiko idibo to de.

O ni "amuwa Ọlọrun la le pe e. Kii ṣe pe eniyan kan dana sun un".

O ṣalaye pe awọn ti bẹrẹ si ni gbaradi fun eto idibo to n bọ ṣugbọn asiko ti wọn maa n muna ọba lo ni nkan yiwọ ti inu ibudo ti wọn n ko awọn ẹrọ to n yẹ kaadi wo si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọgbẹni Rufus bu ẹnu atẹ lu ipo ti ipese ina mọnamọna wa lorilẹede yii pe ko muna doko. O ni bo tilẹ jẹ pe awọn ni nkan to maa ba awọn da abo bo ina mọnamọna ṣugbọn iṣẹlẹ naa fihan pe o ti rẹ ẹ ni.

"Ago meje abọ alẹ ni wọn pe wa pe o ṣẹlẹ, a dupẹ pe o ṣẹlẹ lasiko to ṣẹlẹ tori ẹmi kankan ko ba a lọ".

Torinaa o ni Ọlọrun kii ṣe nkan ko ma faye ọpẹ silẹ tori ẹmi kankan o ba a lọ.

Ọga ajọ INEC ni awọn ti ṣe tan fun idibo. O ni toripe idibo yii wa lasiko iṣẹlẹ Covid 19, igbaradi ati ireti awọn lọdọ awọn oludibo ti yatọ.

"O gbudọ ni kaadi idibo rẹ ati ibomu rẹ, too ba ni i wọn o ni jẹ koo dibo o".

Ọga INEC fi kun pe ẹnikẹni ko gbud w ibomu tabi aṣọ to ni ami ẹgbẹ oṣelu kankan tori asiko ipolongo idibo ti kọja bi bẹẹ kọ ko ni lanfani lati dibo.