Virginity: Kìí ṣe ọmọbìnrin nìkan ni Ọlọ́run pàṣẹ fún láti pa ìbálé mọ́

Published

Arabinrin Temilolu Okeowo ma n polongo kiri pe ki awọn ọmọbinrin pa ibale wọn mọ, ni ibamu pẹlu aṣa Yoruba.

Eyi lo mu ko da ajọ kan to pe ni TGCON, silẹ.

O ma n gbe ipolongo rẹ lọ si ileewe, ile ijọsin ati arin ọja.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC Yoruba, o sọ pe kii ṣe nitori ile ọkọ nikan lo yẹ ki ọmọbinrin pa ibale mọ, o ni o yẹ lati ṣe bẹẹ nitori a ti daabo bo ogo, ọla, ati aasiki ti Ọlọrun da mọ iru ọmọbinrin naa.

Bakan naa lo sọ pe ọrọ pipa ibale mọ ko yọ awọn ọmọkunrin silẹ, bo tilẹ jẹ pe ọmọbinrin nikan ni aṣa Yoruba ma n kọju mọ.

O rọ awọn obi lati mojuto nkan ti awọn ọmọ wọn n wo lori amohunmaworan, ati ori ayelujara.