You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Period party: Àwọn obìnrin kan ṣe ayẹyẹ nkan oṣù l'órí ayélujára
Published
Oriṣiriṣi ipenija ati idẹyẹsi ni awọn obinrin kan maa n koju lasiko ti wọn ba n ṣe nkan oṣu wọn kaakiri agbaye.
Awọn aṣa kan tilẹ n fi oju ti ko tọ ọ wo nkan oṣu obinrin, to si jẹ pe ọpọlọpọ eewọ lo rọmọ ṣiṣe nkan oṣu fun awọn obinrin nibẹ.
Awọn nkan bayii lo mu ki awọn obinrin kan o ko ara wọn jọ lori ayelujara, ti wọn si ṣe ayẹyẹ lati ṣe iwuri fun ara wọn nipa nkan oṣu.