You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Amotekun: Ikọ̀ aláàbò yíì kọjá ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, àwọn ọdẹ àti Àgbẹ̀kọ́yà ló pọ̀ nínú rẹ̀
Kaakiri awọn olu ilu ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba lawọn eeyan ti jade lọjọ Aje lati se iwọde alaafia fun itẹwọgba ikọ alaabo alajumọse lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, taa mọ si Amotekun.
Nibi iwọde naa, ti agbarijọpọ ẹgbẹ ọmọbibi ilẹ Yoruba, Yoruba World Congress, ni asaaju iwọde naa nilu Ibadan, Kunle Adesọkan ti kede pe ẹnikẹni to ko ba fẹ tẹwọgba eto Amotekun, ni ko fẹran ilẹ Yoruba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn ọmọ Yorùbá bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de àláfíà fún ìtẹ́wọ́gbà ètò Amotekun
- Ẹ̀yin ẹ máà wò ó, ó ṣeéṣe kí APC túká lẹ́yìn ìṣèjọ́ba Buhari!
- Ìríwísí àwọn aráàlú bí EFCC ṣe kó afurasí ọmọ yahoo 49 ní Ibadan
- Ọmọ ọdún mẹ́wàá ń jẹ ìrora lẹ́yìn tí ọ̀gá tì í sínú iná àrò búrẹ́dì
- Àwọn ará South-Africa yarí nítorí torí gbọ̀ngàn kọ̀ ìgbéyàwó abo-sábo
Adesọkan tun fikun pe ẹni to ba n ba eto Amotekun ja, lo n ba iran Yoruba ja, to si kesi awọn gomina ilẹ Yoruba lati mase bẹru nitori digbi ni awọn wa lẹyin wọn.
Bakan naa nilu Akurẹ, awọn eeyan to se iwọde nibẹ kede pe ikọ alajumọse Amotekun kọja ọrọ ẹsin nitori awọn ọdẹ ati awọn Agbẹkọya lo wa nibẹ.
Wọn fikun pe ikọ alaabo Amotekun ko wa lati dojukọ ẹya Fulani abi ẹnikẹni, sugbọn gbogbo ẹni to ba n huwa ọdaran ni Amotekun yoo maa doju ija kọ, onitọun ko baa jẹ ẹya Yoruba.