Toll Gate: Ó ṣe pàtàkì kí ìjọba kọ́kọ́ tún ojú popo ṣe naa- Awakọ̀

Published

Kaakiri Naijiria ni awọn eniyan ti n fesi lori igbẹsẹ tuntun ti ijọba fẹ́ gbe lori gbigba owo ibode Laarin awọn iloro.

Latari eyi ni awọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ si ni fi erongba wọn lede lori ẹrọ ayelujara bayi, lẹyin ti ijọba apapọ kede ipadabọ gbigba owo loju popo.

Akọroyin wa fẹsẹ kan de ilu Ibadan ni ipinlẹ Oyo lati wo iha ti ẹgbẹ awọn awakọ kọ si igbesẹ naa.